HYMN 475

H.C 601 8s 7s (FE 501)
“Eniti npa o mo ki yio togbe”
 - Ps. 121:31. LOWO kiniun at’ekun 

   Lowo eranko ibi

   Jo so aw'Egbe Serafu 

   At’om’Egbe kerubu 

   Ninu gbogbo iji to nja 

   A! nibo l'aba sa si

   A! Baba ma fi wa sile 

   Segun Satani fun wa.


2. Ko s'ona ti a ba tun to 

   To le bori ona yi

   Je ka diju si nkan t’aiye 

   Ka laju si nkan t’orun 

   Maje k'aiye fa wa s'ehin 

   Kuro ninu ona Re

   N’nu banuje at’iponju 

   Emi ki o fi O sile.


3. Ade ogo yio je ti nyin 

   T'enyin ko ba sin l’etan 

   Mo se tan mo ti pa nyin po 

   Emi ni Emi Airi

   Sugbon mo wa n‘nu Olanla 

   Mo le pa, mo le gbala 

   Je arowa k’e ma w’ehin 

   K'e le gbere nikehin.


4. lfe to dopin la ntoro

   Fun gbogb' Egbe to papo

   E ja, e segun, e bori

   Laiye yi ati lorun

   Sugbon danwo tun wa l'orun 

   A! bawo ni yio ti ri

   Ka gbo p’o ti je Serafu

   O tun pada nikehin.


5. Ohun ti mo ba pa lase 

   Ma f 'ogbon ori yipada 

   Eniti ko ba gba ‘ran gbo 

   O dabi eniti O

   Ko ‘le re si eti odo 

   Ekun omi de o gba lo

   K'e mase ro p’agbara nyin 

   La ko se fi nyin sile.


6. Jesu se tan lati gba nyin

   O kun f’anu at’ife

   Gb’ara re le patapata

   Ma gb’ekelohun miran 

   Ghohun-gbohun oruko Re 

   Si gba gbogbo orun kan 

   Ke Halleluya s‘Olorun

   Fi 'barale juba Re.


7. E f’Ogo fun Baba loke

   E f’Ogo fun Omo Re 

   Metalokan aiyeraiye

   A juba Oruko Re

  Mase je ki ‘pade wa yi 

  Ko je asan nigbehin 

  F’oju anu wo ‘papo wa 

  K'a le ma pade titi. Amin

English »

Update Hymn