HYMN 478

(FE 504)
Tune: Jeka layo ninu Jesu
“Emi o fe Oluwa” - Ps. 18:11. OLORUN ‘Wo l’agbara mi 

   Emi o feran re

   Iwo l’odi at’abo mi

   Ni igba aini mi.


2. Ni gba ‘rora on ‘banuje 

   Mo toro or-ofe

   Olorun gbo aroye mi 

   Lat’ibi mimo Re.


3. Ati ninu ola‐nla Re 

  O gun awon Kerubu 

   L’apa iye afefe

   L’o si nfo kakiri.


4. O mu mi sibi titeju 

   Ki nle di omnira

   O si pa mi mo nitori 

   Inu Re dun simi.


5. Ona Olorun mo pupo 

   Oro Re ye koro

   Awon t’o ntele ona Re 

   Ni abo t’o daju. Amin

English »

Update Hymn