HYMN 480

10s 11s (FE 506)
Tune: E wole f’Oba ologo julo1. B’IJI lile nja t'iberu gb’ode 

   T'ore gbogbo lo, t'ota si gbogun 

   Ohun to wu ko de ifoya ko si 

   Ileri re ni, Oluwa yio pese.


2. Eiye ki nsise, nwon nri onje je 

   O ye k'a f‘eyi s’eko fun ra wa, 

   Awon ayanfe Re ki y'o s'alaini 

   A ti kowe p'Oluwa y'o pese.


3. Gbat' ogun esu nfe de wa lona 

   T'iberu si fe bori ‘gbagbo wa

   Ko le pa gbolohun yi da l'okan wa 

   Ileri ife Oluwa yio pese.


4. Ki s'agbara wa tab' ise wa 

   Oruko Jesu ni 'gbekele wa 

   Kerubu Serafu, e ma bohun bo 

   N'ijakadi nyin, Oluwa yio pese.


5. Gbat' iku ba de t’emi si nlo

   Oro ‘tunu Re y’o mu wa laja

   Gba Kristi wa lodo wa ifoiya ko si 

   A o ma korin Oluwa yio pese.


6. Ogo fun Baba, Ogo fun Omo 

   Ogo f’Emi Mimo Metalokan 

   L‘agbara Eleda orun on aiye, 

   Jehovah Jire Oluwa y‘o pese. Amin

English »

Update Hymn