HYMN 484

H.C 366 8s. 7s (FE 510)
“Da mi lohun nigbati mo ba npe"
- Ps.4:11. OLUWA da agan l‘ohun 

B'o ti da Hanna l‘ohun

Ma doju ghagbo ti awon

Ti nkepe oruko Re.

Egbe: Da mi l'ohun (2ce)

Ki nle ye ma banuje.


2. Wo gh‘ekun Elisabeti 

Larin awon elegan

O fi Johannu re l‘ekun 

P'Omo Re ma sokun mo.

Egbe: Re mi l'ekun (2ce)

Loju awin ota mi.


3. Ranti ileri Re ‘gbani 

At'ire t‘O fun Noa

Pe k'e ma bisi, k‘e ma re

Ni ori ile aiye. 


Egbe: Da mi l'ohun (2ce)

Iwo Oba Olore.


4. Wo ti ko je k‘eran yagan 

Tab'eiye oju orun

Sanu f'aworan ara Re 

Ki o si si mi ninu.

Egbe: Si mi ninu (2ce)

Olorun Onipin mi.


5. Gbati mo ro okan mi wo 

Mo mo p‘elebi ni mi 

Mo ti to pa fe inu mi

T‘o ko wahala ba mi.

Egbe: Dariji mi (2ce)

Wo Oniyonu julo. Amin

English »

Update Hymn