HYMN 490

C.M.S 429 t.H.C 428 C.M (FE 516)
"E ma ru eru omonikeji nyin" - Gal. 61. WO orisun Ohun rere 

   Awa fe se ‘fe re;

  Ohun wo l‘a le fifun O 

  Oba gbogbo aiye?


2. L'aiye yi, Wo ni otosi 

   T’o je enia Re

   Oruko won n’lwo njewo 

   Niwaju Baba Re.


3. Gba nwon ba nke n’inira won 

   Ohun Re l’awa ngbo

   Gba ba si nse itoju won

   Awa nse 'toju Re.


4. Jesu, masai gba ore wa

   Si f'ibukun Re si

   Ma f’ibukun Re s'ebun wa 

   Fun awon t‘a nfi fun.


5. Fun baba, Omo at’Emi

   Olorun ti a nsin

   Ni ki a ma fi ogo fun

   Titi aiyeraiye. Amin

English »

Update Hymn