HYMN 492

H.C. 527 D.C.M (FE 518)
"Iwo ni ibi ipamo mi" - Ps.32:71. JESU Wo n’ibi isadi mi

   Wo ni mo gbekele

   Oro Re n’Iranlowo mi 

   Emi alailera

   Nko ni ejo kan lati ro 

   Ko s'ohun ti ngo wi

   Eyi to, pe Jesu mi ku 

   Jesu mi ku fun mi.


2. lgba Iji' danwo ba nja 

   T’ota ndojuko mi

   Ite anu n‘isadi mi 

   Nibe n’ireti mi

   Okan mi yio sa to O wa

   Gba ‘banuje ba de

   Ayo okan mi l’eyi pe

   Jesu mi ku fun mi.


3. Larin iyonu t’o wuwo 

   T’enia ko le gba 

   Larin ibanuje okan 

   Ati ‘rora ara

   Kil’ o le funni n’isimi 

   Ati suru b’eyi?

   T'o ns'eleri l'okan mi pe 

   Jesu mi ku fun mi.


4. Gba ohun Re ba si pase

   K'ara yi dibaje

   Ti emi mi, b'isan omi

   Ba si san koja lo

   B'ohun mi ko tile jale 

   Nigbana, Oluwa,

   Fun mi n'ipa ki nle wipe 

   Jesu mi ku fun mi. Amin

English »

Update Hymn