HYMN 5

C.M.S 7, H.C. t.H.C 258 S.M. (FE 22)
"Lale loro ati losan li emi o ma 
gbadura" Ps. 55:7


1. WA s'adura oro

   Kunle k'a gbadura; 

   Adura ni opa Kristiani,

   Lati b'Olorun rin.


2. Losan, wole labe 

   Apat' aiyeraiye;

   Itura ojiji Re dun,

   Nigbat' orun ba mu.


3. Je ki gbogbo ile,

   Wa gbadura l'ale

   Ki ile wa di t'Olorun,

   Ati 'bode orun.


4. Nigbati od'oganjo

   Jek'a wi l'emi, pe 

   Mo sun, sugbon okan mi ji

   Lati ba O sona. Amin 

English »

Update Hymn