HYMN 512

"Mase beru, Emi o wa pelu nyin 
titi de opin" - Matt. 28:20
1. EGBE Seraf e ma beru 

   Ki yio si nkan

   B’esu gbe tasi re si wa 

   Ki yio si nkan

   Jesu Kristi I’Ogagun wa 

   Esu yio wole labe Re

   Ki yio sai nkan.


2. B’a ba nrin l‘afonifoji

   Ki yio si nkan

   B’iku npa l’otun npa l’osi 

   Ki yio si nkan

   Mase foiya, Egbe Seraf 

   Te siwaju b’omo ogun 

   Krist’Ogagun wa niwaju 

   Ki yio si nkan.


3. Kil’ohun ti mba nyin leru 

   Egbe Seraf

   Gbati Jesu wa pelu wa

   Ki yio si nkan 

   Sagbadura, te siwaju

   Oke nla yio di petele 

   Aiye ko le ri wa gbe se 

   Ki yio si nkan.


4. Egbe Seraf te siwaju 

   larin ina 

   Ina Esu ko le jo wa 

   Dajudaju

   Bi Sedraki, Mesaki ati 

   Abednigo ninu ina

   Be la o duro pelu Jesu 

   Ki yio si nkan.


5. Egbe Seraf, eho fayo 

   Ki yio si nkan

   Jesu ti fo 'tegun esu 

   Dajudaju

   Ogo, iyin fun Oba wa, 

   To ra wa pada lowo ‘ku 

   To so wa d’ominira lai 

   Kabiyesi. Amin

English »

Update Hymn