HYMN 514

H.C 315 C.M (FE 539) 
"Ki Kristi le ma gbe okan nyin 
nipa igbagbo” - Efe 3:171. JESU, kiki ironu Re

   Fi ayo kun okan 

   Sugbon k’a ri O lo dun ju 

   K'a simi lodo Re.


2. Enu ko so, eti ko gbo
  
   Ko ti okan wa ri

   Or’ko, t’o sowon, t‘o dun bi 

   Ti Jesu Oluwa.


3. Ireti okan ti nkanu 

   Olore elese

   O seun f’awon ti nwa O 

   Awon t’o ri O yo.


4. Ayo won, enu ko le so 

  Eda ko le rohin 

  Ife Jesu, b’o'ti po to 

  Awon Tire l'o mo.


5. Jesu, Wo ma je ayo wa 

   Wo sa ni ere wa

   Ma je ogo wa nisiyi 

   Ati titi lailai. Amin

English »

Update Hymn