HYMN 518

C.M.S 334 H.C 320 C.M (FE 543)
"Oruko Jesu Omo Mimo Re” lse. 4:30
1. ORUKO kan mbe ti mo fe 

   Mo fe ma korin re 

  Iro didun ni l’eti mi 

  Oruko didun ni.


2. O so ife Olugbala 

   T’o ku lati ra mi

   O so t’eje re ‘yebiye 

   Etutu f’elese.


3. O so ti iyonu baba 

   T'O ni si Omo Re

   O m’ara mi ya, lati la 

   Aginju aiye ja.


4. Jesu, Oruko ti mo fe

   T‘o si dun l’eti mi,

   Ko‘ s’eni mimo kan l’aiye 

   T‘o mo b’o ti po to.


5. Oruko yi j’orun didun 

   L'ona egun t’a nrin 

   Yio tun ona yangi se 

   T'o lo s’odo Olorun.


6. Nibe pelu awon mimo 

   Ti nwon ‘bo nin’ese? 

   Emi o korin titun ni 

   T’ife Jesu si mi. Amin

English »

Update Hymn