HYMN 519

H.C 327 D.C.M (FE 544)
“A dari ese re ti o po ji i, nitori
o ni ife pupo” - Luku 7:47 1. JESU, Oluwa, a fe O,

   Tori gbogbo ebun

   Nt'owo re da lat' oke wa

   B'iri si gbogbo aiye

   A yin O nitori wonyi

   Ki ise fun won nikan

   Ni awon omo-odo Re 

   Se ngbadura si O.


2. Awa fe O, Olugbala 

   Tori 'gba t’a sako 

   lwo pe okan wa pada 

   Lati t' ona iye,

   Gba t’a wa ninu okunkun 

   T’a rin ninu ese

   Wo ran imole Re si wa 

   Lati f'ona han wa.


3. Baba orun, awa fe O,

   Nitori Wo fe wa 

   Wo ran Omo Re lati ku

   Ki awa le n’iye

   Gbat’ a wa labe ‘binu Re 

   Wo fun wa n’ireti

   Bi ese t‘a da ti po to 

   Be l‘ o dariji wa. Amin

English »

Update Hymn