HYMN 52

(FE 69)
"Ki O si gba lorun ibugbe re! Gbo
ki O si dariji" - 1 Oba 8:30
1. BABA MIMO jowo gbo, gbe omo Re,

   METALOKAN MlMO OBA OGO, 

   Egbe aladura ipe na ndun

   Egbe Serafu t'aiye e mura. 

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo rin,

      F‘oju okan wo agbala ni

      Nib'OLUDANDE wa nwipe 

      BABA MIMO dariji.


2. Ogoji odun ni BABA fi gb‘ebe, 

   Ka le gb'egbe lo logo yi dide 

   Ogoji Odun ni OMO fi bebe 

   Lati d‘egbe Serafu yi sile. 

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo...


3. BABA OLUPESE jo pese fun wa, 

   OLUGBOGBE EDA gbogb' edun wa, 

   OLUBUKUN-JULO leni ranse na, 

   METALOKAN ranse rere si wa. 

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo...


4. Egbe akorin e tun ohun nyin se, 

   Ke Halleluya s’Oba Olore

   Egbe Aladura e t'esu mole 

   K’EMI MlMO s'amona Egbe wa. 

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo...


5. Enyin ariran nin’egbe Serafu 

   Mase boju w‘ehin esu wa nibe, 

   Mura gin k'esu ma fa o sehin 

   J'eni kikun laiberu enia.

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo...


6. Awa dupe Iowo OBANGUI 

   OLORUN ALANU buk'egbe wa, 

   JEHOVAH SABAOTH

   jowo sunmo wa,

   Segun gbogb‘ota ‘le ati t‘ode.

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo...


7. Ope lo ye omo Egbe Kerubu, 

   Fun anu re lori gbogb'egbe wa 

   Elom ran jade nile o d'oku

   A dupe fun abo to fi mbo wa.

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo...


8. F’OGO fun BABA MIMO loke orun, 

   E tun f'ogo fun OMO RE pelu

   E f'ogo EMl to dari wa 

   Metalokan Mimo lope ye fun

Egbe: Wa ore mi, wa ka jumo... Amin

English »

Update Hymn