HYMN 520

O t.H.C. 53 I.M (FE 545)
"Awafe enitori onMefe wa" - I John 4:191. AWA ko orin ife Re 

  Obangiji Oba Ogo

   Ko s’ohun ti lalasi Re 

   Ola Re ko si nipekun.


2. N'nu ife l'o s’eda aiye 

   O da enia sinu re

   Lati ma s’akoso gbogbo 

   E korin ‘fe Eleda wa.


3. Lojojumo l’ O ntoju wa

   O si mbo, O si nsike wa 

   Beni ko gba nkan lowo wa 

   Korin ‘yin s’onibu ore.


4. O ri wa ninu okunkun 

   Pe, a o mo ojubo Re 

   N'ife O fi ona han wa 

   E korin ife Olore!


5. N’ife O fi Jesu fun wa 

   Omo bibi Re kansoso 

   O wa ra wa lowo ese 

   A yin fe Re Olugbala!


6. lfe Re ran oro Re wa 

   lfe Re l'o si wa leti 

   lfe Re si mu wa duro 

   E korin ore-ofe Re.


7. Gbogbo eda kun fun ‘fe Re 

   Oluwa wa, Oba aiye 

   Gbogbo agbaiye, e gberin 

   Orin ife Olorun wa. Amin

English »

Update Hymn