HYMN 526

O.t.H.C. 60 7s (FE 551)
"Ki ife ara ki o pe titi‘"
 - Heb. 13:11. JESU, Iwo ni a nwo 

   K’a repo l‘oruko Re

   Alade alaiia

   Mu k‘ija tan l’arin wa.


2. Nipa ilaja Tire

   Mu idugbolu kuro 

   Jek'a dapo si okan 

   F'itegun Re sarin wa.


3. Jek'a wa ni okan kan 

   K'a se anu at‘ore 

   K'a tutu l'ero l‘okan 

   Gege bi Oluwa wa.


4. K‘a s‘aniyan ara wa 

   K‘a ma reru ara wa 

   K‘a f‘apere fun ljo 

   B'Olugbagbo ti gbe po.


5. K‘a kuro ni ibinu

   K‘a simi le Olorun

   K‘a so ti ibu ife

   At‘iwa giga mimo. Amin

English »

Update Hymn