HYMN 527

C.M.S 345 O.S 57 8s 7. (FE 552)
"Eniti o ba fe Olorun, o fe arakunrin re"
- 1John. 4:211. ARA, e je ka jumo rin 

   N'ife on alafia

  A ha le ma tun bere pe 

  O to k’a ba f'ija mo? 

  Ni irepo, ni irepo 

  L’ayo, ife y'o fi po.


2. B‘a ti nrin lo sile je ka 

   Ran ‘ra wa lowo l‘ona 

   Ota ka wa nibi gbogbo 

   S'ona gbogbo l’a dekun.

   lse wa ni, ise wa ni 

   K’a ma ran ‘ra wa l’eru.


3. Nigbat’ a rohun Baba se 

   T'o ti fi ji, t‘o nfiji

   Ara, ko to k’awa k‘o ko 

   Lati ma f’ija sile

   K’a mu kuro, k’a mu kuro 

   Ohun’ ba mu ‘binu wa.


4. K’a gb‘omonikeji wa ga 

   Ju b’a ba ti gbe ‘ra wa 

   K’a fi keta gbogbo sile 

   K’okan wa si kun fun ‘fe 

   Yio ro wa, yin ro wa

   B‘a wa n’irepo laiye. Amin

English »

Update Hymn