HYMN 529

O.t.H.C 483 C.M (FE 554) 
"E ma fi rere fe ara nyin"
 - Rom.12:101. ALAFlA ni f'okan na 

   Nibiti fe gbe wa 

   Kerubu pelu Serafu

   E feran ara yin.


2. Gegebi Kerubu orun

   Pelu Seruf‘ orun

   Awon ni nwon yi ‘te na ka 

  Nwon nyin Baba logo.


3. Asan ni gbogbo ‘gbagbo je 

  Bi ko si ‘fe nibe

  Ese yio joba lokan wa 

  B‘ife ko si nibe.


4. lfe nikan ni yio r‘opin

   E feran ara nyin

   Ma banuje, ma b’ohun bo 

   Ade yio je tiwa.


5. Sugbon ife ni nwi bayi 

   E feran ara nyin

   Nipa ife a o ri Baba 

   L'oke orun lohun.


6. Jesu Olugbala, owon 

   Fun Kerubu n’ife

   Gege bi Kerubu orun 

   Pelu Seraf' orun.


7. Jehovah Nissi Baba wa 

   Pe wa n'Tire l‘oke 

   Emi Mimo ‘daba orun 

   Jowo f‘ona han ni.


8. Jehovah-Rufi Baba wa

   Fun wa l’okun ‘lera

   Ka le jo fi ‘yin fun Baba 

   Gege b’awon t’orun. Amin

English »

Update Hymn