HYMN 53

(FE 70)
“E fi iberu sin Oluwa" - Ps. 2:111. ‘K’E wole f'Oba Ologo 

   Eni O ngbe ‘nu imole 

   T’oju elese kan ko ri 

   Dariji, Dariji.


2. Gbogbo omo Egbe Serafu, 

   L'okunrin at’obinrin 

   K'a ronu ese ti a da,

   K'a toro 'dariji.


3. B‘a ba mo'ra wa l'elese, 

   K'a jewo re la je tan,

   K'a ronu k’a si pawada, 

   Baba yio dariji.


4. Ese aini ‘fe l'o poju 

   Larin wa ba ti kunle

   Esu l‘o ngb' ogun re ti wa 

   Baba jo dariji.


5. Ninu ‘wa wa ati ‘se wa, 

   Ninu oro enu wa,

   “Nu gigan enikeji wa 

   Dariji, Daniji.


6. Gbogbo wa Iati f‘oju ri, 

   ‘Wo lo ran ‘mole si wa, 

   Lati fi ona Re han wa 

   Dariji, Daniji.


7. Bi ko ba se anu Re ni 

   Ka to de ‘nu ‘mole yi 

   Esu ba l’ayo lori wa 

   Dariji, Dariji.


8. Bi ko ba s'esu t'o ngb’ogun 

   A le f‘ibi s'olore,

  Jowo pa ise esu run

  Dariji, Daniji.


9. Wo ti 'ya ti Jesu wa je 

   ‘Ranti ogun eje Re, 

   Nin'ogba Gestesmani 

   Dariji, Dariji.


10. A dupe p‘O ti gbo tiwa 

    Ma je k'a tun d’ese mo,

    Tun wa yipada Oiuwa,

    K’a l‘ayo l'ojo ‘kehin. Amin

English »

Update Hymn