HYMN 543

H.C. 411 C.M. (FE 569)
“Emi li ona, otito ati iye" - John14:61. IWO l’Ona-odo re ni 

   Awa o ma sa bo

   Awon t’o nsaferi Baba 

   Yio wa s’odo Re.


2. Iwo l’Oto-oro Tire 

   L’o le f’ogbon fun wa 

   Iwo nikan l’ o le ko wa 

   T’O si le we okan.


3. lwo n’Iye: iboji Re

   Fi agbara Re han

   Awon t‘o gbeke won le O 

   Nwon bo lowo iku.


4. lwo l'Ona, Oto, Iye

   Jek’a mo ona Re

   K'a mo otito at’lye

   T’ayo re ko l’opin. Amin

English »

Update Hymn