HYMN 545

C.M.S 123 t.S 154. 8.7 (FE 571)
“Emi mo pe, ninu mi ko, si nkan
to dara" - Rom. 7:181. BABA orun! emi fe wa 

   N’iwa mimo l'ododo 

   Sugbon ife eran-ara 

   Ntan mi je nigba gbogbo.


2. Alailera ni emi se

   Emi mi at’ara mi

   Ese gbagbogbo ti mo nda 

   Wo mi l'orun bi eru nla.


3. Ofin kan mbe li okan mi 

   ‘Wo papa l'o fi sibe 

   Tori eyi ni mo fi fe 

   Tele'fe at'ase Re.


4. Sibe, bi mo fe se rere 

   Lojukanna, mo sina 

   Rere l’oro Re ma so 

   Buburu l'emi si use.


5. Nigba pupo ni mo njowo 

   Ara mi fun idanwo

   Bi atile nkilo fun mi 

   Lati gafara f’ese.


6. Baba orun, lwo nikan 

   L'o to lati gba mi la 

   Olugbala ti o ti ran

   On na ni ngo gba mora.


7. Fi Emi Mimo Re to mi 
 
   S’ona titun ti mba gba 

   Ko mi, so mi, k’O si to mi 

   Iwo Emi Olorun. Amin

English »

Update Hymn