HYMN 548

C.M.S 433 t.H.C 433 L.M (FE 574)
“Enyin nfi iku Oluwa han titi yio fi de”
 - 1Kor.11:251. LI oru ibanuje ni

   T'agbara isa oku nde 

   S‘Omo iyanu Olorun 

   Ore ta A fun ota Re.


2. Ki ‘waiya ‘ja Re to bere 

   O mu akara, O si bu 

   Wo ife n’ise Re gbogbo 

   Gb’oro ore-ofe t’O so.


3. Eyi l’ara t’a bu f’ese 

   Gba, k’e si je onje iye 

   O si mu ago, O bu wain 

   Eyi majemu eje Mi.


4. O wipe, Se yi tit’ opin 

   N’iranti iku ore nyin 

   Gbati e ba pade, ma ranti 

   Ife Olorun nyin to lo.


5. Jesu, awa nyo s’ase Re 

   Awa f’iku Re han l’orin 

   K’Iwo to pada, ao ma je 

   Onje ale Odagutan. Amin

English »

Update Hymn