HYMN 55

H.C. 305, 11s (FE 72)
"K O n dide fun iranlowo mi" - Ps. 35:21. OLORUN Eleda/jowo sunmo wa, 

   Awa omo Re de/lati juba Re, 

   Ran Serafu t'orun/ati Kerubu; 

   Lati wa ba wa pe/Iati jo yin O.


2. Baba Olubukun/bukun wa loni

   Je k'ipade oni/le mu eso wa,

   Je ki omo 'mole/to wa l'okunkun 

   Wa sinu imole/lati ri ‘gbala.


3. Tikala Re wasu/fun agutan Re,

   Maje ki nwon segbe, pe won sodo Re, 

   Maje k‘ina Re ku/ n‘ile Yoruba 

   Jeki ina Re ma/tan nibe titi.


4. Awon ti 'Wo ti pe/ni ilu Eko

   Ati gbogbo aiye/ma fi won sile, 

  Oko ‘gbala kehin/to tun gbe kale 

  Maje k'eranko wo/l‘akoko ti wa.


5. Enyin Egbe Seraf'/ati Kerubu 

   E ma je ko re nyin, e mase sole 

   Gbe ‘da 'segun soke, Jesu ti segun;

   Nipa agbara Re/ awa yio segun.


6. Sugbon k'a s‘otito/ni ilana Re, 

   Yio si gbe wa nija, yio duro ti wa,

   K‘a fara da iya, ka te siwaju

   On to gbo t'Abraham/yio si gbo ti wa.


7. Jesu Olugbala/Ore Elese

   Je ka se ife Re/ka te s'ona Re, 

   Je ka fi iwa wa/p’elomiran wa, 

   Ko si fun wa n'ife/larin ara wa.


8. A mbe O, Eleda, Olorun tiwa 

   Fun awon ariran/ninu Egbe yi, 

   F‘iran didan han won, si tun yan 

   kun won,

   Mase jeki esu/f'iran re han won.


9. Nigbat’o ba si di/ojo ikehin

   T‘oju gbogbo aiye, yio pe sodo Re, 

   Maje k'oju ti wa, ma je ka sokun, 

   Jek’awa Serafu/ke Halleluya. Amin

English »

Update Hymn