HYMN 558

H.C 295 H.C 154 t.H.C 400 
C.M (FE 585)
“Iwo ti bo aso ofo mi kuro”
 - Ps. 30:111. A dupe lowo Oluwa, 

   E ki mi ku ewu 

   Fun irin ajo mi yi na 

   Ope fun Oluwa.


2. Kerubu pelu Serafu 

   F’Ogo f’oruko Re 

   F’eni to d’Egbe yi sile 

   On li Oba Ogo.


3. E ho, e yo, korin ogo 

   Jesu Oba ogo

   Oruko Re kari aiye 

   O mu mi lo, mo bo.


4. Ope lo ye O, Oluwa 

   F’abo Re l’ori mi 

   Yika orile ede gbogbo 

   Ogo f’oruko Re.


5. K’okiki Re yika aiye 

   ma bo, Oluwa mi 

   Oba Mimo, Oba aiku 

   Eni Metalokan.


6. E korin Ologo Mimo 

   Ope ni f’Oluwa

   A lo, a bo, l’alafia 

   Mo dupe f’Oluwa.


7. E ke Halle, Halleluyah

   F'OIorun Kerubu

   E ke Halle, Halleluyah 

   S’Olorun Serafu. Amin

English »

Update Hymn