HYMN 564

O t.H.C 326 6.8s (FE 591)
"Oluwa Ii Olusagutan mi, emi ki yio
sa alaini” - Ps. 23:11. OLUSAGUTAN y'o pese

   Y’O fi papa tutu bo mi 

   Owo re y'o mu ‘ranwo wa 

   Oju re y'o si ma so mi,

   Y'o ma ba mi kiri losan 

   Loru y’o ma dabobo mi.


2. Nigbati mo nrare kiri 

   Ninu isina l‘aginju

   O mu mi wa si petele 

   O fi ese mi le ona 

   Nib'odo tutu nsan pele 

   Larin papa oko tutu.


3. Bi mo tile nrin koja lo 

   Ni afonifoji iku

   Emi ki o beru-keru 

   ‘Tori lwo wa pelu mi 

   Ogo at'opa Re y’o mu 

   Mi la ojiji iku ja.


4. Lehin are ija lile

   Wo te tabili kan fun mi

   Ire at'anu ni mo nri

   Ago mi si nkunwosile

   Wo fun mi n’ireti orun 

   Ibugbe aiyeraiye mi. Amin

English »

Update Hymn