HYMN 568

H.C 164 t.H.C 323 C.Ms (FE 595)
“Enoku si ba Olorun rin"- Gen.5:241. EMI ‘ba le f’iwa pele 

   Ba Olorun mi rin

   Ki mni imole ti nto mi 

   Sodo Odagutan!


2. Ibukun ti mo ni ha da

   Gba mo ko mo Jesu? 

   Itura okan na ha da

   T'oro Kristi fun mi?


3. Alafia mi nigbana

   Ranti re ti dun to! 

   Sugbon nwon ti b’afo sile 

   Ti aiye ko le di.


4. Pada, Emi Mimo, pada 

   Ojise itunu

   Mo ko ese t‘o bi O n’nu 

   T’o le O lokan mi.


5. Osa ti mo fe rekoja 

   Ohun t’o wu k’o je

   Ba mi yo kuro lokan mi 

   Ki nle sin 'Wo nikan.


6. Bayi ni ngo b’Olorun rin 

   Ara o ro mi wo!

   Mole orun y‘o ma to mi 
 
   Sodo Odagutan. Amin

English »

Update Hymn