HYMN 576

H.C 354 S.M (FE 603)
"E je alagbara ninu Oluwa, ati
ninu ipa agbara re" - Efesu 6:101. OM-OGUN Krist, dide

   Mu hamoran nyin wo 

   Mu'pa t‘Olorun fi fun nyin 

   Nipa ti Omo re.


2. Gbe pa Olorun wo 

   T’Oluwa om‐ogun, 

   Enit’o gbekele Jesu 

   O ju asegun lo.


3. Ninu ipa Re nla

   On ni ki e duro

   Tori k’e ba le jija na 

   E di hamora nyin.


4. Lo lat’ipa de ‘pa 

   Ma je ma gbadura

   Te agbara okunkun ba 

   E ja, k’e si segun.


5. Lehin ohun gbogbo 

   Lehin gbogbo ija

   K’e le segun n'ipa Kristi 

   K‘e si duro sinsin. Amin

English »

Update Hymn