HYMN 579

H.C 373 8s 7s (FE 606)
"Awon eni-irapada Oluwa yio pada, 
nwon o si wa si Sion ti awon ti 
orin” ‐ Isa.51:111. NINU oru ibanuje

   L’ awon egbe ero nrin 

   Nwon nkorin reti at’ayo 

   Nwon nlo sile ileri.


2. Niwaju wa nin'okunkun 

   Ni imole didan ntan 

   Awon arakorin nsate 

   Nwon nrin lo Ii aifoiya.


3. Okan ni imole orun 

   Ti ntan s’ara enia Re 

   Ti nle gbogbo eru jina 

   Ti ndan yi ona wa ka.


4. Okan ni iro ajo wa 

   Okan ni igbagbo wa 

   Okan l’eni t’a gbekele 

   Okan ni ireti wa.


5. Okan l’orin t’egberun nko 

   Bi lati okan kan wa

   Okan n’ija okan l‘ewu 

   Okan ni irin orun.


6. Okan ni inu didun wa 

   L’ebute ainipekun 

   Nibiti Baba wa orun 

   Y‘o ma joba titi lai.


7. Nje k‘a ma nso arakonrin 

   T‘awa ti agbelebu

   E jek'a ru, k’a si jiya

   Tit’ ao fi ri simi.


8. Ajinde nla fere de na

   Boji fere si sile

   Gbogbo okun y’o si tuka 

   Gbogbo lala y’o si tan. Amin

English »

Update Hymn