HYMN 58

S.S & 173 (FE 75)s 8s 7s
“Emi o si ba nyin da Majemu”
- Gen. 9:111. OBA TI ki ye Majemu

   F'ore ofe Re fun wa,

   Majemu ti a ba O da,

   Ki awa ko le mu se.

Egbe: Nitori iku Messaiah

      Jowo ko sanu fun wa. 2ce


2. Oba Mimo Oba Ogo,

   Wo l‘awa nfi iyin fun

   Kerubu ati Serafu

   S'ope odun titun yi.

Egbe: Nitori iku Messaiah...


3. Alaileso jek'o s'eso

  Ninu odun t‘awa yi

  Alaigbagbo je ko gbagbo

  Ki gbogbo wa di yiye.

Egbe: Nitori iku Messaiah...


4. Oba Mimo Jehofa NLA

   Gb'ope Ajodun wa yi,

   Seri Ibukun Re sori

   Omode at‘agba wa.

Egbe: Nitori iku Messaiah...


5. Pese f’awon alairise,

   Pese omo fun agan

   Fi ilera fun alaisan

   K'omo Re mase rahun.

Egbe: Nitori iku Messaiah...


6. F'agbara Re f 'Egbe Serafu,

   Lati sin O de opin

   Mase je k‘ise wa laiye

   Ja s‘asan niwaju Re.

Egbe: Nitori iku Messaiah... Amin

English »

Update Hymn