HYMN 582

ORO ALAFIA
Tune: YMHB 793 - 6s 8.4
1. ORO Alafia

   La fi sin nyin ara 

   K’alafia bi odo nla 

   Ma ba nyin gbe.


2. N'nu oro adura

   Af’ awon ara wa 

   Le ise Oluwa lowo 

   Ore toto.


3. Oro ife didun 

   L'a fi p'odigbose 

   Ife wa ati t'Olorun 

   Y‘o ba won gbe.


4. Oro'gbagbo lile

   Ni igbekele wa 

   Pe, Oluwa y’o se ranwo 

   Nigba gbogbo.


5. Oro'reti didun 

   Y’o mu Ipinya wa dun 

   Y‘o so ayo t’o le dun ju 

   Ayo t' aiye.


6. Odigbose, ara

   N’ife at’igbagbo

   Tit' ao fi tun pade loke 

   N'ile wa orun. Amin

English »

Update Hymn