HYMN 584

H.C 309 P.M (FE 610)
"E gba ajaga mi sorun nyin..eriyin 
o si fi isinmi fun okan nyin" - Matt 11:291. MO simi le Jesu 

   ‘Wo ni mo gbekele

   Mo kun fun ese at’osi 

   Tani mba tun to lo?

   Li okan aiya re nikan 

   L'okan are mi simi le.


2. Iwo Eni Mimo! 

   Baba simi n’nu Re

   Eje etutu ti O ta 

   L’O si mbebe fun mi 

   Egun tan, mo d’alabukun 

   Mo simi ninu Baba mi.


3. Eru ese ni mi!

   ‘Wo l'o da mi n’ide

   Okan mi si fe lati gba 

   Ajaga Re s’orun 

   Ife Re t’o gba aiya mi 

   So ‘se ati lala d’ayo.


4. Opin fere de na 

   Isimi orun mbo

   Ese at’ irora y‘o tan

   Emi o si de ‘le 

   Ngo jogun ile ileri

   Okan mi o simi lailai. Amin

English »

Update Hymn