HYMN 586

C.M.S 385, Christian Choir 
25 P.M (FE 612)
'Emi ngba gbe nkan wonni ti o
wa Iehin, mo si nnoga wo nkan 
wonni ti o wa niwaju” - Filli 3:13
1. GBEKELE Olorun re, 

   K’o ma nso! k’o ma nso! 

   Di ‘leri re mu sinsin

   K‘o ma nso!

   Mase se oruko Re, 

   B’o tile mu egan wa 

   Ma tan ihin Re kale 

   Si ma nso!


2. O ti pe O si se Re? 

   Sa ma nso! Sa ma nso

   Oru mbo wa mura sin! 

   Sa ma nso!

   Sin n’ife at’igbagbo 

   Gbekele agbara Re

   Fi ori ti de opin 

   Sa ma nso!


3. O ti fun o ni ‘rugbin 

   Sa ma nso! Sa ma nso! 

   Ma gbin 'wo o tun kore 

   Sa ma nso!

   Ma sora, si ma reti 

   L‘enu ona Oluwa 

   Y'o dahun adura re, 

   Sa ma so!


4. O ti wipe opin mbo 

   Sa ma nso! Sa ma nso! 

   Nje fi eru mimo sin! 

   Sa ma nso!

   Krist l’atilehin re 

   On na si ni onje re 

   Y‘o sin o de 'nu ogo 

  Sa ma nso!


5. Ni akoko die yi 

   Sa ma nso! Sa ma nso! 

   Jewo Re ni ona re 

   Sa ma nso!

   K ari okan Re n’nu re 

   K’ife Re je ayo re

   L’ojo aiye re gbogbo 

   Si ma nso! Amin

English »

Update Hymn