HYMN 594

C.M.S 395 H.C 344 L.M (FE 620) 
"Awon oluranlawo ninu Kristi Jesu"
- Rom. 16:31. KO mi, Oluwa, bi a ti

   Je gbohungbohun, oro Re 

   B’O ti wa mi, je k‘emi wa 

   Awon omo Re t’o ti nu.


2. To mi, Oluwa, ki nle to 

   Awon asako si ona

   Bo mi, Oluwa, ki nle fi 

   Manna Re b‘awon t’ebi npa.


3. Fun mi l’agbara, fi ese 

   Mi mule lori apata

   Ki nle na owo igbala 

   S’awon t’o nri sinu ese.


4. Ko mi, Oluwa, ki nle fi 

   Eko rere Re k’elomi 

   F’iye f’oro mi, k’ o le fo 

   De ikoko gbogbo okan.


5. F'isimi didun Re fun mi 

   Ki nle mo, bi i ti ye lati 

   Fi pelepele soro Re 

   Fun awon ti are ti mu.


6. Jesu, fi ekun re kun mi 

   Fi kun mi li opolopo

   Ki ero ati oro mi

   Kun fun ife at'iyin Re.


7. Lo mi, OLuwa, an’emi

   Bi o ti fe, nigbakugba 

   Titi em’o fi r'oju Re

   Ti ngo pin ninu ogo Re. Amin

English »

Update Hymn