HYMN 600

110 8s 7s (FE 626)
“Ke rara, mase dasi, gbe ohun 
Re soke bi ipe" - Isa. 58:1
1. ENYIN enia Olorun 

   Okunkun yi aiye ka 

   So hun ayo ti Jesu 

   Ni gbogb’ orile ede.

Egbe: Ihin ayo, Ihin ayo 

     Ti ‘toye Olugbala.


2. Ma tiju ihinrere Re, 

   Agbara Olorun ni

   N’ilu t’a ko wasu Jesu 

   Kede dasile f’onde.

Egbe: Idasile, ldasile

     Bi t’awon Omo Sion.


3. B’aiye on Esu dimolu 

   S‘ise Olugbala wa,

   Ja fun ise Re, ma f’oiya 

   Mase beru enia.

Egbe: Nwon nse lasan, nwon 

     nse lasan,

     lse Re ko le baje.


4. Gbati ewu nla ba de si nyin 

   Jesu y‘o dabobo nyin 

   Larin ota at’alejo 

   Jesu y‘o je Ore nyin.

Egbe: ltoju Re, Itoju Re

      Y'o pelu nyin tit’t opin. Amin

English »

Update Hymn