HYMN 602

C.M.S 403 S. 20 8s 9s. (FE 628)
"Jesu ti Nasareti li o nkoja lo"
 - Luku 18:371. EREDI irokeke yi

   Ti enia ti nwo koja?

   Jojumo n’iwojopo na

   Eredi re ti nwon nse be?

   Nwon dahun lohun jeje pe

   Jesu ti Nasaret’ l‘o nkoja

   Nwon dahun lohun jeje pe

   Jesu ti Nasaret' l‘o nkoja.


2. Tani Jesu? ese ti On

   Fi nmi gbogbo ilu bayi?

   Ajeji Ologbon ni bi

   Ti gbogb‘ enia nto lehin?

  Nwon si tun dahun jeje pe

  Jesu ti Nasaret' lo nkoja

  Nwon si dahun jeje pe

  Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.


3. Jesu On na l’O ti koja

   Ona irora wa laiye

   ‘Bikibi t’O ba de, nwon nko

   Orisi arun wa ‘do Re

   Afoju yo b’o ti gbo pe

  Jesu ti Nasaret’ lo nkoja

  Afoju yo b’ o ti gbo pe

  Jesu ti Nasaret’ lo nkoja.


4. On si tun de! nibikibi

   Ni awa si nri ‘pase Re

   O nrekoja lojude wa

   O wole lati ba wa gbe

   Ko ha ye k’a f’ayo ke pe?

   Jesu ti Nasaret’ lo nkoja

   Ko ha ye ka f ’ayo ke pe?

   Jesu ti Nasaret’ lo nkoja.


5. Ha, e wa eyin t’orun nwo

   Gba ‘dariji at’itunu

   Enyin ti e ti sako lo

   Pada, gba ore-ofe Baba

   Enyin t’a danwo abo mbe

   Jesu ti Nasaret’ lo nkoja

   Enyin t’ a danwo abo mbe

   Jesu ti Nasaret’ lo nkoja.


6. Sugbon b’iwo ko ipe yi

   Ti o si gan ife nla re

   On yio pehinda si O

   Yio si ko adura re

  O pe ju n’igbe na y’o je

  Jesu ti Nasaret‘ lo nkoja

  O pe ju n’igbe na y’o je

  Jesu ti Nasaret; lo nkoja. Amin

English »

Update Hymn