HYMN 605

D7s 6s
1. GBATI ‘danwo yi mi ka

   Odo Krist' ni mo nlo

   Ni okan aya Re ni

   Ibi isadi mi

   Mo s’okan mi paya fun

   Omo gbogb’ edun mi

   Bi mo ti nso nkan wonyi

   O m’edun mi kuro.


2. Gbati mo kun fun eru

   Ti mo nsunkun pere

   O tan ibanuje mi

   O le eru mi lo

   O r'ewu t‘o yi mi ka

   Ati ailera mi

  O fun mi l’ohun ija

  Lati segun ese.


3. L’odo Kristi ni un o lo

   Nibi t'o wu ko je

   Un o sa ma wo oju Re

   O daju pe un o ri 

   Gb'ayo tabi banuje

   Ohun to wu ko je 

   Odo re sa ni un o lo

   Oun y'o si to mi wa. Amin

English »

Update Hymn