HYMN 61

7s 6s (FE 78)
Tune: Duro, Duro fun Jesu.1. BABA WA ti mbe l'orun

   Owo loruko Re,

   Ife tire ni ka se

   Bi nwon ti nse lorun

   Fun wa l'onje ojo wa

   ‘Dari ese ji wa,

   Gba wa lowo idanwo

   Gba wa lowo ewu.


2. Iwo to gbo t'Elija

   Leba odo Kedron

   lwo to gbo ti Daniel

   Ko gbo ti wa loni,

   Fun wa niru agbara

   To fi f'awon Apostle

   K'awa le wulo fun O

   Ka jere bi ti won.


3. Fun wa lokan igbagbo

   Ti ki y’o ye lailai

   Ka gbekele O titi,

   Ao fi r’ oju Re,

   Je ka le ni ireti

   Ninu Iwo nikan

   Ka nife s’enikeji,

   Ka si n’iwa pele.


4. Baba a si tun mbe O,

   Ani fun OIon' wa,

   Ko fi Emi meje Re

   Se ‘tura f ’okan re,

  Je ki awa le ma rin

  Lona to nto wa si

  Ko le ko wa de Canaan

  Niwaju Ite re.


5. Iwo to gbo ti Sedrak,

   Mesak, Abednego

   Gbo t’awa Egbe Serafi,

   Gbat’a ba nkepe O

   Fi agbara Re wo wa

   Bi ti woli isaju

   Ka ni ‘gboya bi ti won

   Ka segun aiye yi.


6. Awon Omo Isreal,

   Ninu rin ajo won,

   Iwo lo ns’amona won,

   Ati abo fun won,

   Bi nwon ti ndese si O,

   Be lo ndariji won,

   Jowo ko dariji wa,

   Awa Egbe Serafu.


7. Olorun Abrahamu,

   Olorun Isaaki

   Ati Olorun Jakobu

   Awa f’ope fun O

  Ogo, iyin, olanla

  S'Eni Metalokan

  Halleluyah’s Olorun

  Aiye ainipekun. Amin

English »

Update Hymn