HYMN 614

H.C 218 t..C 96. D.7s 7s (FE 640)
"Ohun eniti nkigbe ni iju” - Isa.40:31. OHUN ti ndun l'aginju 

   Ohun alore ni 

   Gbo b‘o ti ndun rara pe 

   E ronupiwada!

   Ohun na ko ha dun to? 

   Ipe na ko kan o!

   Kil’ o se arakunrin 

   Ti o ko fi mira?


2. Ijoba ku si dede 

   Ijoba Olorun

   Awon t'o ti fo so won 

   Nikan ni yio gunwa 

   Ese t’o ko fi nani 

   Ohun alore yi

   Ti dun l'eti re tantan 

   Pe ronupiwada.


3. Abana pelu Fapar 

   Le je odo mimo 

   Sugbon ase wenumo 

   Jordan nikan l’o ni 

   Ju ero re s’apakan 

   Se ase Oluwa

   Wa s’inu adagun yi 

   We k’o si di mimo.


4. Kin’ iba da o duro? 

   Awawi kan ko si

   Wo odo, wo Johanu re 

   Ohun gbogbo setan

   O pe ti o ti njiyan

   O ha bu Emi ku? 

   Elese gbo alore

   Si ronupiwada. Amin

English »

Update Hymn