HYMN 619

C.M.S 448 t.H.C 34 C.M (FE 645) 
“Eje Jesu Kristi omo re ni nwe wa 
nu kuro ninu ese wa gbogbo" - 1Joh. 1:71. NIHINYI n’isimi gbe wa 

   Niha re ti eje nsan

   Eyi nikan n’ireti mi

   Pe Jesu ku fun mi.


2. Olugbala Olorun mi 

   Orisun f‘ese mi

   Ma f‘eje re won mi titi 

   K’emi le di mimo.


3. We mi, si se mi ni Tire 

   We mi, si je temi

   We mi, ki s‘ese mi nikan 

   Owo at’okan mi.


4. Ma sise lokan mi, Jesu 

   Titi gbagbo y'o pin

   Tit’ ireti y‘o fi dopin 

   T'okan mi yio Simi. Amin

English »

Update Hymn