HYMN 621

H.C 457 t. H.C 14. L.M (FE 647)
“Emi o gba nyin, Emi o si je Baba
fun iyin...Omokunrin Mi ati omobinrin 
Mi l'Oluwa olodumare wi" - 2Kor. 6:17,181. BABA, Apat’ agbara wa 

   Ileri eniti ki ‘ye

   Sinu agbo enia Re 

   Jo, gba omo yi titi lai.


2. Ati f’omi yi sami fun 

   Li oruko Metalokan 

   A si ntoro ipo kan fun 

   Larin awon omo Tire.


3. A sa l’ami agbelebu 

   Apere iya ti O je 

   Kristi, k’ileri re owuro 

   Je ‘jewo ojo aiye re.


4. Fifunni, k’iku on iye

   Ma ya omo Re lodo Re 

   K’on je om'ogun Re to toto 

   Orn‘odo Re, Tire lailai. Amin

English »

Update Hymn