HYMN 625

H.C 294 6.Ss (FE 651) 
"Emi se ara mi bi enipe tabi 
arakunrin" - Ps. 35:141. ORE aiye ki lo jamo 

   Ohun asan ni mo mo si 

   Ko si alanu bi Jesu,

   Alawoko, Olorun ni 

   Adawunse ko, Olorun ni 

   Enia ko, Olorun ni.


2. O ye ki nfi Jesu s’ore 

   Ko si ore kan bi Jesu 

   Jesu to fe wa d’oju ku

   Babalawo ko Olorun ni 

   Awole ko, Olorun ni 

   Enia ko, Olorun ni.


3. Nko ni eniti mba kepe 
 
   Mo wo waju mo wo ehin 

   Ko tile si alabaro

   Onisegun ko, Olorun ni 

   Awole ko Olorun ni 

   Enia ko, Olorun ni.


4. Sugbon mo ro mo O, Jesu 

   Emi ki yio fi O sile

   Jesu ma sai ran mi lowo

   Alawo ko, Olorun ni 

   Enia ko, Olorun ni 

   Akunleyan lo mba mi ja.


5. Gbati mo joko n’ile mi 

   Esu wa d’eru b’okan mi 

   Sugbon Jesu gbemi leke

   Nwon ni mo ku l’araiye so 

   Nwon l’o ti ku l’araiye so 

   Sugbon Jesu da mi sile.


6. Alairise, ko ma binu 

   Alaisan ma so ‘reti nu 

   Jesu yio mu nyin lara da

   Alawo ko, Olorun ni 

   On’segun ko, Olorun ni 

   Enia ko, Olorun ni.


7. K’a f’ogo fun Baba l’oke 

   K’a f'ogo fun Omo pelu 

   Ogo ni fun Metalokan

   Olosanyin ko, Olorun ni 

   Aworawo ko, Olorun ni 

   Jesu nikan lo to kepe. Amin

English »

Update Hymn