HYMN 63

SM (FE 80)
“Da mi lohun nigbati mo ba npe" - Ps. 4:11. BABA jo gbo temi

   Mo wole lese Re

   ‘Wo to nwosan to ndariji,

   Jowo gbadura wa.


2. Olorun Oluwa,

   Jehofa Oba mi,

   ‘Wo to tedo sinu ‘mole

   Ajuba O’ko Re.


3. Tali oba ti aiye?

   Jesu Emmanuel,

   Gbongbo Jesse Eni ‘Yanu

   Ran ‘ranwo Re si mi.


4. Mimo Mimo julo

   Oba Olugbala

   Alagbara ninu orun

   Ranti majemu Re.


5. Lowuro gbo temi,

   Losan gbo ebe mi,

   Loju ale gbat’orun wo

   Jowo gbo ebe mi.


6. Ogo fun Baba wa,

   Ogo ni fun Omo Re

   Ogo ni fun Emi Mimo

   Metalokan lailai. Amin

English »

Update Hymn