HYMN 638

C.M.S 502, H.C 516 C.M (FE 664)
"Se igbala nisiyi, emi mbe O, Oluwa"
- Ps. 118:251. OLORUN gb’okan mi loni 

   Si ma se ni Tire

   ki nma sako lodo Re mo 

   ki nma ye lodo re.


2. Wo, mo wole buruburu

   lese agbelebu

   kan gbogbo ese mi no gi 

   Ki Krist’ j‘ohun gbogbo.


3. F’ore ofe orun fun mi 

   Si se mi ni Tire

   Ki nle r'oju Re t'o logo 

   Ki nma sin n’ite Re.


4. K'ero, oro, at’ise mi 

   Je Tire titi lai,

   Ki nfi gbogb’ aiye mi sin O, 

   K’iku je isimi.


5. Ogo gbogbo ni fun Baba 

   Ogo ni fun Omo 

   Ogo ni fun Emi Mimo

   Titi ainipekun. Amin

English »

Update Hymn