HYMN 641

t. H.C 2nd Ed.502. C.M (FE 667)
“Ore ofe ki o wa pelu nyin" - 2Tim. 4:221. F'ore-ofe Re ba wa gbe 

   Jesu Olugbala

   Ki eni arekereke

   K'o ma le kolu wa.


2. F'oro mimo Re ba wa gbe 

   Jesu iyebiye

   K'a ri igbala on iye 

   Lohun bi nihinyi.


3. Fi ‘bukun Tiure ba wa gbe 

   Oluwa Oloro

   Fi ebun orun rere Re 

   Fun wa l’opolopo.


4. Fi pamo Tire ba wa gbe

   Iwo Alagbara

   K‘awa k'o le sa ota ti

   K’aiye k’o ma de wa.


5. Fi otito Re ba wa gbe 

   Olorun Olore

   Ninu ponju wa ba wa re 

   Mu wa fi ori ti.


6. F‘alafia re ba wa gbe 

   Nigbat‘iku ba de 

   N'iseju na, so fun wa pe 

   lgbala nyin ti de. Amin

English »

Update Hymn