HYMN 646

Luk. 14:15-24 L.M (FE 672)1. WA, elese, s’ase rere 
 
   K’a je alabaje Jesu

   K’enikeni ma ku sehin

   Olorun pe gbogbo eda.


2. Oluwa ran mi wa pe nyin

   Fun gbogbo nyin ni ipe na

   Wa, gbogbo aiye, elese wa 

   N‘nu Krist’ ohun gbogbo se tan.


3. Wa, emi t'ese npon loju 

   Tinwa isimi kakiri

   Aro, afoju, otosi

   N‘nu Krist‘ e o r’itewogba.


4. We, s'alabaje ase na 

   Kuro l‘ese, simi le Krsiti 

   To ore Olorun re wo 

   Je ara Re, mu eje Re.


5. Asako emi, mo pe nyin 

   Ohun mi ‘ba je le to nyin 

   Logan e ba r’idalare

   E ba si ye, n’tori Krist'ku.


6. Gba oro mi bi t’Olorun 

   Wa sodo krist. ki e si ye 

   Jek’ife Re ro okan nyin 

   E ma jek'iku Re j’asan.


7. Wa nisiyi, ma se duro

   Oni l'ojo itewogba

   Wole, ma se ko ipe re 

   F’ara re f’Eni ku fun o. Amin

English »

Update Hymn