HYMN 648

H.C 441 10s (FE 674)
"Ara mi ti a fi fun nyin Ii eyi, e ma
se eyi ni iranti mi" - Luku 22:19


1. SUNMOHIN, k’o gba Ara Oluwa 

   K’o mu Eje mimo t’a ta fun o.


2. Ara at’eje na l'o gba la

   N’itura okan, f'ope f’Olorun.


3. Elebun igbala, Omo Baba 

   Agbelebu Re fun wa n'isegun.


4. A fi On rubo fun tagba tewe 

   On tikare l‘Ebo, On l’Alufa.


5. Gbogb’ ebo awon Ju laiye ‘gbani 

   J‘apere ti nso t’Ebo yanu yi.


6. On I’Oludande, On ni Imole 

   On nf‘Emi ran awon Tire lowo.


7. Nje, e f’okan igbagbo sunmo‘ hin 

   Ki e si gba eri igbala yi.


8. On l'o nsakoso enia Re Iaiye 

   On l‘o nf’iye ainipekun fun wa.


9. On f’onje orun f’awon t’ebi npa 

   Omi iye fun okan ti npongbe.


10. Onidajo wa, Olugbala wa

    Pelu wa ni ase ife re yi. Amin

English »

Update Hymn