HYMN 652

H.C 448 S.M (FE 678)
“O mu mi wa sibi ase" - Orin Sol.2:41. ASE ife Orun 

   Ore-Ofe l’o je

   K’a je akara, k’a mu wain 

   Ni ‘ranti Re Jesu.


2. Oluwa, a nduro 
 
   Lati ko eko na

   T’ohun ti mbe l’aiya Baba 

   At'ore-ofe Re.


3. Eri-okan ko to 

   lgbagbo l'o fi han 

   Pe adun akara iye 

   Ekun ife re ni.


4. Eje ti nsan f’ese 

   L'a r’apere re yi 

   Eri si ni li okan wa 

   Pe lwo feran we.


5. A! eri die yi

   Bi o ba dun bayi

   Y‘o ti dun to l'oke orun 

   Gbat' ba r'oju Re?


6. Lati ri oju Re

   lati ri b'O ti ri

   K'a a si ma so ti ore Re 

   Titi aiyeraiye. Amin

English »

Update Hymn