HYMN 654

K. 117 t.H.C 320 C.M (FE 680) 
“Igbeyawo kan" - John 2:11. NI’BI ase Igbeyawo 

   Kana ti Galili

   Nibe Jesu sise yanu 

   O so omi di waini.


2. Jesu wa fi ara re han 

   Ni bi gbeyawo yi

   Ki o si fi ipese Re 

   Fun won lat’ ihin lo.


3. Fun won n’ife at’irepo 

   T’aiye ko le baje
   
   Si jeki nwon fi okan won 

   Fun ise isin Re.


4. Ki nwon ma ran ‘ra won lowo 

   Nipa ajumose

   Ki Ogo Re si le ma han

   Ni arin ile won.


5. A! fi won s'abe iso Re 

   Olupamo julo

   Olorun Olodumare

   Fi abo Re be won.


6. Ogo fun Baba at'Omo 

   Ati f’Emi Mimo

   Ogo ni fun Metalokan 

   L’aiye ati l’orun. Amin

English »

Update Hymn