HYMN 655

t.H.C 247 7s 6s (FE 681)
“Ki Oluwa ki o sanu fun nyin ki o si 
busi fun nyin" - Ps. 67:1
Tune: Ire ta sun ni Eden1. BABA Olodumare 

   A ntoro anu Re 

   S’ori arakunrin 

   At'arabinrin yi.


2. S‘Okan oko on aya 

   F'iberu Re fun won

   Ki nwon n'ife ara won 

   Ni ojo aiye won.


3. Ran esi rere si wa 

   K’awa si le mo pe 

   Gbogbo eto oni yi 

   Je didun inu Re.


4. Iru ojo bi on

   Jehovah Jireh wa 

   Wa lati f’ibuku fun 

   Awon enia Re.


5. Se nwon ni abiyamo 

   Ki nwon ko si ma re 

   Eranko ati eiye 

   Nwon mbi lopolopo.


6. F'ayo on alalfia pelu 

   Pelu itelorun

   S'ile awon omo Re 

   Pese fun aini won.


7. Ki adun lona gbogbo 

   Yi won ka lat’ oni 

   K’ire ma ba won titi 

   K'a aiye ma le ya won.


8. Baba Onibu-ore

   Ran ore Re si won

   Mu won bori gbogbo ota 

   Si je Olorun won. Amin

English »

Update Hymn