HYMN 658

C.M.S 504 t.H.C 564 C.M (FE 584)
"A si pe Jesu ati awon omo-ehin Re 
pelu sibi igbeyawo" - John 2:21. JESU f'ara han nitoto 

   Nibi ase ‘yawo 

   Oluwa, awa be O, wa 

   F’ara Re han nihin.


2. Fi ibukuu Re fun awon 

   Ti o dawopo yi 

   F’ojurere wo ‘dapo won 

   Si bukun egbe won.


3. F’ebun ife kun aiya won 

   Fun won n‘itelorun

   Fi alalfia Re kun won 

   Si busi ini won.


4. F’ife mimo so won d’okan 

   Ki nwon f 'ife kristi

   Mu aniyan ile fere

   Nipa ajumose.


5. Jeki nwon ran ‘ra won lowo 

   Ninu ibugbe won

   Ki nwon si ni omo rere

   Ti y’o gbe ‘le won ro. Amin

English »

Update Hymn