HYMN 659

H.C 523 6.8.4. (FE 685) 
"Simi ninu Oluwa ki o si fi suru duro
de” - Ps.37:71. SIMI le Oluwa - egbo 

   Orin duru orun

   Simi le ‘fe Re ailopin 

   Si duro je.


2. Simi, iwo oko to gba 

   Iyawo re loni

   Ninu Jesu, ‘yawo re ni 

   Titi aiye.


3. Iwo ti a fi owo re

   F’oko n’nu ile yi 

   Simi, Baba f’edidi Re 

   S’ileri nyin.


4. E simi, enyin ore won 

   T’e wa ba won pejo 

   Olorun won ati ti nyin 

   Gba ohun won.


5. Simi, Jesu Oko Ijo 

   Duro ti nyin nihin 

   Ninu idapo nyin, O nfa 

   Ijo mora.


6. E simi Adaba Mimo 

   M’oro Re se n’nu wa 

   Simi le ‘fe Re ailopin 

   Si duro je. Amin

English »

Update Hymn