HYMN 664

C.M. (FE 690)
“Ofln enu Re dara fun mi” - Ps.119:72
Anfani isin Olorun mimo lati igba ewe.1. ALABUKUN FUN l’omo na 

   Lati igba ewe

   Ti ki rin l’ona iparun 

   Ti mberu Olorun.


2. K’a fi ara wa f’Olorun 

   Lat’ igba ewe dun 

   Ebun giga n’itanna je 

   Gba to ba sese nyo.


3. K’a t’ewe beru Oluwa 

   Rorun lopolopo

   Bi elese ti ndagba to 

   L’okan nwon si nle to.


4. Ka gbo ti isin Olorun 

   Lati igba ewe

   N’nu ewe pupo ni a nyo 

   A si fun-ni n’ipa.


5. Olorun Olodumare

   A f’ara wa fun O

   K'a a je tire lat’ ewe lo 

   Titi d’opin aiye.


6. K’ise adura at’iyin

   Je ise aiye mi 

   Lojo iku, k’yio je ki nye 

   Lati f’ayo r’orun. Amin

English »

Update Hymn